Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:41 - Yoruba Bible

41 Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

41 Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:41
9 Iomraidhean Croise  

Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.


Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé; tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀!


sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́; dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’ Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́, nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀.


“Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”


Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.


Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan