Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:3 - Yoruba Bible

3 Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:3
16 Iomraidhean Croise  

“Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín, mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi.


Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi.


Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.


àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.


Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.”


Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.”


Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.”


Lẹ́yìn tí wọ́n tún halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n dá wọn sílẹ̀, nítorí wọn kò rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n níyà, nítorí àwọn eniyan. Gbogbo eniyan ni wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọrun fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀.


A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.


Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan