Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:21 - Yoruba Bible

21 Ṣugbọn àwa kò mọ̀ bí ó ti ṣe wá ń ríran nisinsinyii. Ẹ bi í, kì í ṣe ọmọde, yóo fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bí ó ti rí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnrarẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:21
7 Iomraidhean Croise  

Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn.


Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji.


Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?”


Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé, “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí; ati pé afọ́jú ni a bí i.


Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ.


Nítorí èyí ni àwọn òbí ọkunrin náà ṣe sọ pé, “Kì í ṣe ọmọde, ẹ bi òun alára léèrè.”


Ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iniasi tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún mẹjọ; kò lè dá ara gbé nílẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan