Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:2 - Yoruba Bible

2 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olùkọ́ni, ta ni ó dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yìí ni, tabi àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n fi bí i ní afọ́jú?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:2
9 Iomraidhean Croise  

O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi.


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni. Àwọn mìíràn ní Elija ni. Àwọn mìíràn tún ní Jeremaya ni tabi ọ̀kan ninu àwọn wolii.”


Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’


Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́.


Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí?


Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”


Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá.


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde.


Nígbà tí àwọn ará Mẹlita rí ejò náà tí ó ń ṣe dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ Paulu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkunrin yìí. Ó yọ ninu ewu òkun, ṣugbọn Ọlọrun ẹ̀san kò gbà pé kí ó yè.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan