Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:7 - Yoruba Bible

7 Bí wọ́n ti dúró tí wọ́n tún ń bi í, ó gbé ojú sókè ní ìjókòó tí ó wà, ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí kò bá ní ẹ̀ṣẹ̀ ninu yín ni kí ó kọ́ sọ ọ́ ní òkúta.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:7
18 Iomraidhean Croise  

Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.


Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́?


Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀hún bá dáhùn pé, “Ẹnikẹ́ni kò sọ̀rọ̀ bí ọkunrin yìí rí!”


Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó bi obinrin náà pé, “Obinrin, àwọn dà? Ẹnìkan ninu wọn kò dá ọ lẹ́bi?”


Ó bá tún bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀.


Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn.


Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan.


Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare.


Nítorí náà, ronupiwada. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo wá láìpẹ́, n óo sì fi idà tí ó wà lẹ́nu mi bá wọn jà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan