Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:41 - Yoruba Bible

41 Irú ohun tí baba yín ṣe ni ẹ̀ ń ṣe.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í ṣe ọmọ àlè, baba kan ni a ní, òun náà sì ni Ọlọrun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

41 Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà: a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:41
17 Iomraidhean Croise  

O óo wí fún un pé, Èmi, OLUWA wí pé, ‘Israẹli ni àkọ́bí mi ọkunrin.


Ìwọ ni baba wa. Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá, tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀. Ìwọ OLUWA ni baba wa, Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ.


Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa, amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa.


OLUWA ní, “Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi, tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára, kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù, láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ, ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.


“Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni? Ṣé ọmọ mi àtàtà ni? Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀, nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí; dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀.


Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.”


“Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’


Àwọn ará Juda jẹ́ alaiṣootọ sí OLUWA, àwọn eniyan ti ṣe ohun ìríra ní Israẹli ati ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Juda ti sọ ibi mímọ́ tí OLUWA fẹ́ràn di aláìmọ́; àwọn ọmọkunrin wọn sì ti fẹ́ àjèjì obinrin, ní ìdílé abọ̀rìṣà.


Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba mi ni mò ń sọ, ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́ lọ́dọ̀ baba yín ni ẹ̀ ń ṣe.”


Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.


“Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú.


Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí, ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi? Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín, Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀.


Kí á má dàbí Kaini tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí ó pa arakunrin rẹ̀. Kí ló dé tí ó fi pa á? Nítorí iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣugbọn ti arakunrin rẹ̀ dára.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan