Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:39 - Yoruba Bible

39 Wọ́n sọ fún un pé, “Abrahamu ni baba wa.” Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọ Abrahamu ni yín, irú ohun tí Abrahamu ṣe ni ẹ̀ bá máa ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

39 Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣẹ Abrahamu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

39 Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!” Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:39
13 Iomraidhean Croise  

Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi.


Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo.


Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?”


Mo mọ̀ pé ìran Abrahamu ni yín, sibẹ ẹ̀ ń wá ọ̀nà láti pa mí, nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè ninu yín.


Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi.


Inú Abrahamu baba yín dùn láti rí àkókò wíwá mi, ó rí i, ó sì yọ̀.”


ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà.


Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní.


Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.”


Tí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, a jẹ́ pé ẹ jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, ẹ sì di ajogún ìlérí.


kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan