Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:34 - Yoruba Bible

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:34
16 Iomraidhean Croise  

(Kò sí ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ burúkú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Ahabu, tí Jesebẹli aya rẹ̀, ń tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láti ṣe iṣẹ́ burúkú.


Eniyan burúkú a máa jìn sinu ọ̀fìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a sì bọ́ sinu ìyọnu nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ.


Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.”


Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.”


Nítorí èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ tún rí ààyè jọba ninu ara yín tí ẹ óo fi máa fààyè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.


Ẹ kò mọ̀ pé ẹrú ẹni tí ẹ bá ń gbọ́ràn sí lẹ́nu lẹ jẹ́, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fara yín ṣẹrú fún, tí ẹ sì ń jíṣẹ́ fún? Ẹ lè fi ara yín ṣẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó fikú san án fun yín; ẹ sì lè fìgbọràn ṣọ̀gá fún ara yín, kí ó sì fun yín ní ìdáláre.


Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.


Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀.


Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa. Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀.


ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun.


Nígbà náà ẹ̀ ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ayé yìí, ẹ̀ ń gbọ́ràn sí aláṣẹ àwọn ẹ̀mí tí ó wà ninu òfuurufú lẹ́nu, àwọn ẹ̀mí wọnyi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí ninu àwọn ọmọ tí kò gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu.


Nítorí nígbà kan rí, àwa náà ń ṣe wérewère, à ń ṣe àìgbọràn, ayé ń tàn wá jẹ, a jẹ́ ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a sì ń jẹ ayé ìjẹkújẹ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. À ń hùwà ìkà ati ìlara. A jẹ́ ohun ìríra fún àwọn eniyan. Àwa náà sì kórìíra ọmọnikeji wa.


Wọ́n ṣèlérí òmìnira fún àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹrú ohun ìbàjẹ́ wọn ni àwọn fúnra wọn jẹ́, nítorí tí ohunkohun bá ti borí eniyan, olúwarẹ̀ di ẹrú nǹkan náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan