Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:22 - Yoruba Bible

22 Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Kò ṣá ní pa ara rẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:22
11 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀gàn àwọn onírera ti pọ̀ jù fún wa; yẹ̀yẹ́ àwọn onigbeeraga sì ti sú wa.


Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan; ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.


Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi, àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo.


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


Ọpọlọpọ ninu wọn sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ ti dàrú. Kí ni ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí?”


Àwọn eniyan dá a lóhùn pé, “Nǹkan kọ lù ọ́! Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”


Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni?


Àwọn Juu sọ fún un pé, “A kúkú ti sọ pé ará Samaria ni ọ́, ati pé o ní ẹ̀mí èṣù!”


Àwọn Juu wá sọ fún un pé, “A wá mọ̀ dájú pé o ní ẹ̀mí èṣù wàyí! Abrahamu kú. Àwọn wolii kú. Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní tọ́ ikú wò laelae.’


Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan