Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:17 - Yoruba Bible

17 Ninu òfin yín a kọ ọ́ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí ẹni meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:17
13 Iomraidhean Croise  

Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”


“Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn.


Bí kò bá gbọ́, tún lọ bá a sọ ọ́, ìwọ ati ẹnìkan tabi ẹni meji; gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ẹ̀rí ẹnu eniyan meji tabi mẹta ni a óo fi mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’


Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’


Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.


Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ.


Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí?


Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo.


“Ẹ̀rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo péré kò tó láti fi dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùnkẹ́sùn tí wọ́n bá fi kàn án, tabi ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ tí ó bá ṣẹ̀. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta, kí ẹ tó lè dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùn kan.


Bí ẹni meji tabi mẹta bá jẹ́rìí pé ẹnìkan ṣá Òfin Mose tì, pípa ni wọn yóo pa olúwarẹ̀ láì ṣàánú rẹ̀.


À ń gba ẹ̀rí eniyan, ṣugbọn ẹ̀rí Ọlọrun tóbi ju ti eniyan lọ; nítorí ẹ̀rí Ọlọrun ni, tí ó jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀.


N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan