Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:15 - Yoruba Bible

15 Ojú ni ẹ̀ ń wò tí ẹ fi ń ṣe ìdájọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:15
17 Iomraidhean Croise  

Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ẹ̀bi fún aláre, tí ẹ sì tẹ òdodo mọ́lẹ̀.


Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò.


Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po.


Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?”


Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò bá pa á mọ́, èmi kò ní dá a lẹ́jọ́, nítorí n kò wá sí ayé láti ṣe ìdájọ́, ṣugbọn mo wá láti gba aráyé là.


Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.”


Nítorí Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti dá aráyé lẹ́bi bíkòṣe pé kí aráyé lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìgbàlà.


Ẹ má wo ojú eniyan ṣe ìdájọ́, ṣugbọn ẹ máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́.”


Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”]


Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún.


Ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí lè wádìí ohun gbogbo, ṣugbọn eniyan kan lásán kò lè wádìí òun alára.


Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́.


Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú.


Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan