Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:12 - Yoruba Bible

12 Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:12
31 Iomraidhean Croise  

Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú, mo sì wà láàyè.’


Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn, OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.


yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú, kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́.


Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo, ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.


OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun, láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ. Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè kí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.


Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín, tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu, tí ń rìn ninu òkùnkùn, tí kò ní ìmọ́lẹ̀, ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀.


Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.


Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.”


Ṣugbọn ní ti ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù mi, oòrùn òdodo yóo tàn si yín pẹlu ìwòsàn mi, ẹ óo máa yan káàkiri bí ọmọ ẹran tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀.


“Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́.


ìmọ́lẹ̀ láti fi ọ̀nà han àwọn kèfèrí ati ògo fún Israẹli, eniyan rẹ.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.


Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.


Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn.


Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.


Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú.


Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, olúwarẹ̀ yóo mọ̀ bí ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ ti Ọlọrun, tabi bí ó bá jẹ́ pé ti ara mi ni mò ń sọ.


Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”


Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé: ‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ”


Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.”


Wọ́n dàbí ìsun omi tí ó ti gbẹ, ati ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. Ọlọrun ti pèsè ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri fún wọn.


Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́.


Bí a bá wí pé a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀, tí a bá ń gbé inú òkùnkùn, òpùrọ́ ni wá, a kò sì ṣe olóòótọ́.


Ìgbì omi òkun líle ni wọ́n, tí ó ń rú ìwà ìtìjú wọn jáde. Ìràwọ̀ tí kò gbébìkan ni wọ́n. Ààyè wọn ti wà nílẹ̀ fún wọn, ninu òkùnkùn biribiri títí ayé ainipẹkun.


Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn angẹli tí wọn kọjá ààyè wọn àkọ́kọ́, tí wọ́n kúrò ní ipò tí Ọlọrun kọ́ fi wọ́n sí. Ẹ̀wọ̀n ayérayé ni Ọlọrun fi dè wọ́n mọ́ inú òkùnkùn biribiri títí di ọjọ́ ńlá nnì tíí ṣe ọjọ́ ìdájọ́.


Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan