Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:11 - Yoruba Bible

11 Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”]

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹ̃li emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:11
27 Iomraidhean Croise  

“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé, ‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́.


Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.


Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i, ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.


Rárá o! Mò ń sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.


Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.”


Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn angẹli Ọlọrun yóo máa yọ̀ nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada.”


Ó yẹ kí á ṣe àríyá, kí á sì máa yọ̀, nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè, ó ti sọnù, a sì tún rí i.’ ”


Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ayọ̀ tí yóo wà ní ọ̀run nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada ju ti ìtorí àwọn olódodo mọkandinlọgọrun-un tí kò nílò ìrònúpìwàdà lọ.


Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mo wá pè sí ìrònúpìwàdà.”


Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn.


Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.”


Nítorí Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti dá aráyé lẹ́bi bíkòṣe pé kí aráyé lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìgbàlà.


Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.”


Ojú ni ẹ̀ ń wò tí ẹ fi ń ṣe ìdájọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.


Àbí o fi ojú tẹmbẹlu ọpọlọpọ oore Ọlọrun ni, ati ìfaradà rẹ̀ ati sùúrù rẹ̀? O kò mọ̀ pé kí o lè ronupiwada ni gbogbo oore tí Ọlọrun ń ṣe,


Èwo ni tèmi láti dá alaigbagbọ lẹ́jọ́? Ṣebí àwọn onigbagbọ ara yín ni ẹ̀ ń dá lẹ́jọ́? Ọlọrun ni ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn alaigbagbọ. Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.


“Ẹ yan àwọn adájọ́ ati àwọn olórí tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà yín, ní àwọn ìlú yín, wọn yóo sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn eniyan.


Ẹ tọ àwọn alufaa ọmọ Lefi lọ, kí ẹ sì kó ẹjọ́ yín lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà ní ipò onídàájọ́ ní àkókò náà. Ẹ ro ẹjọ́ yín fún wọn, wọn yóo sì bá yín dá a.


Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan