Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:7 - Yoruba Bible

7 Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:7
27 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó bi í pé, “O tún ti rí mi kọ́, ìwọ ọ̀tá mi?” Elija bá dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún ti rí ọ; nítorí pé o ti fa ara rẹ kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ burúkú níwájú OLUWA.


Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.” Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”


Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi, ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.


Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí, kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.


ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára, gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”


àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀, tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà, tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan.


Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ, fún ẹni tí ayé ń gàn, tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra, iranṣẹ àwọn aláṣẹ, ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde, àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀. Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo, Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”


Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé, “Ogun ati ìparun dé!” Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.


Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò,


Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan.


OLUWA ní, “N óo wá ba yín láti ṣe ìdájọ́; n óo wá jẹ́rìí mọ́ àwọn oṣó ati àwọn alágbèrè, àwọn tí wọn ń búra èké ati àwọn tí wọn kì í san owó ọ̀yà pé, àwọn tí wọn ń ni àwọn opó ati àwọn aláìníbaba lára, ati àwọn tí wọn ń ṣi àwọn àlejò lọ́nà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi.”


“Nígbà tí gbogbo eniyan bá ń ròyìn yín ní rere, ẹ gbé, nítorí bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wolii.


Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé.


Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú.


Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni.


Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín!


Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun.


Láti inú ayé ni àwọn yìí ti wá; nítorí náà, wọ́n ń sọ nǹkan ti ayé, àwọn aráyé sì ń gbọ́ tiwọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan