Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:52 - Yoruba Bible

52 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àbí ará Galili ni ìwọ náà? Lọ wádìí kí o rí i pé wolii kankan kò lè ti Galili wá!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

52 Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili bí? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

52 Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:52
11 Iomraidhean Croise  

Wọ́n dáhùn pé, “Yàgò lọ́nà fún wa, ṣebí àjèjì ni ọ́ ní ilẹ̀ yìí? Ta ni ọ́ tí o fi ń sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa? Bí o kò bá ṣọ́ra, a óo ṣe sí ọ ju bí a ti fẹ́ ṣe sí wọn lọ.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ti Lọti mọ́ ara ìlẹ̀kùn títí ìlẹ̀kùn fi fẹ́rẹ̀ já.


Sedekaya wolii, ọmọ Kenaana bá súnmọ́ Mikaaya, ó gbá a létí, ó ní, “Ọ̀nà wo ni Ẹ̀mí OLUWA gbà fi mí sílẹ̀, tí ó sì ń bá ìwọ sọ̀rọ̀.”


Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.”


Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”


Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́.


Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Òun ni Mesaya.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Báwo ni Mesaya ti ṣe lè wá láti Galili?


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan