Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:51 - Yoruba Bible

51 “Ǹjẹ́ òfin wa dá eniyan lẹ́bi láìjẹ́ pé a kọ́ gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, kí á mọ ohun tí ó ṣe?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

51 Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:51
8 Iomraidhean Croise  

“O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké.


Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.


“Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn.


Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.”


Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’


Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan