Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:47 - Yoruba Bible

47 Àwọn Farisi bá bi wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin náà ti di ara àwọn tí ó ń tàn jẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

47 Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

47 Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:47
8 Iomraidhean Croise  

ó ní òun ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, kò lè gbà yín sílẹ̀.


títí di ìgbà tí òun óo fi ko yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí yóo dàbí tiyín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati waini, ilẹ̀ tí ó kún fún oúnjẹ ati ọgbà àjàrà, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ má baà kú. Ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín, kí ẹ máa rò pé OLUWA yóo gbà yín.


Ó ní nítorí náà, kí wọn má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn wọ́n jẹ, tabi kí ó ṣì wọ́n lọ́nà báyìí. Ó ní kí wọn má gbọ́ ohun tí ó ń sọ rárá, nítorí pé kò sí oriṣa orílẹ̀-èdè kan tí ó tó gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ òun tabi lọ́wọ́ àwọn baba òun, kí á má wá sọ pé Ọlọrun tiwọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀yin náà ṣe ń fi àṣà ìbílẹ̀ yín rú òfin Ọlọrun?


Wọ́n ní, “Alàgbà, a ranti pé ẹlẹ́tàn nì sọ nígbà tí ó wà láàyè pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹta òun óo jí dìde.


Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.”


Bí a ti ń gba ọlá, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìtìjú. Bí a ti ń gba èébú, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìyìn. Àwọn ẹlòmíràn kà wá sí ẹlẹ́tàn, bẹ́ẹ̀ sì ni olóòótọ́ ni wá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan