Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:42 - Yoruba Bible

42 Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:42
17 Iomraidhean Croise  

Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi.


OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi, èyí tí kò ní yipada; ó ní, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.


‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae, n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”


Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese, ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.


“Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà.


OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”


Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu.


Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé.


‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda, o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda. Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde, tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ”


Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya.


Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni.


Ṣugbọn eléyìí kò lè jẹ́ Mesaya, nítorí a mọ ibi tí ó ti wá. Nígbà tí Mesaya bá dé, ẹnikẹ́ni kò ní mọ ibi tí ó ti wá.”


OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.”


Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.”


Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”


Saulu bi í léèrè pé, “Ọmọ, ta ni baba rẹ?” Dafidi dáhùn pé, “Ọmọ Jese ni mí, iranṣẹ rẹ, tí ń gbé Bẹtilẹhẹmu.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan