Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:36 - Yoruba Bible

36 Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí tí ó sọ pé, ‘Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, níbi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀?’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

36 Ọrọ kili eyi ti o sọ yi, Ẹnyin ó wá mi, ẹ kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, ẹnyin kì yio le wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

36 Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:36
11 Iomraidhean Croise  

Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?”


Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.


Nikodemu bi í pé, “Báwo ni a ti ṣe lè tún ẹni tí ó ti di àgbàlagbà bí? Kò sá tún lè pada wọ inú ìyá rẹ̀ lẹẹkeji kí á wá tún un bí!”


Nikodemu wá bi í pé, “Báwo ni nǹkan wọnyi ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”


Àwọn Juu wá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i nítorí ó wí pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá.”


Gbolohun yìí dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàrin àwọn Juu. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe lè fún wa ní ẹran-ara rẹ̀ jẹ?”


Ọpọlọpọ tí ó gbọ́ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí le, kò sí ẹni tí ó lè gba irú rẹ̀!”


Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, ibi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀.”


Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.”


Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan