Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:23 - Yoruba Bible

23 Ẹ̀yin ń kọ ilà ní Ọjọ́ Ìsinmi kí ẹ má baà rú òfin Mose, ẹ wá ń bínú sí mi nítorí mo wo eniyan sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Bi enia ba ngbà ikọla li ọjọ isimi, ki a ma bà rú ofin Mose, ẹ ha ti ṣe mbinu si mi, nitori mo mu enia kan larada ṣáṣa li ọjọ isimi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:23
9 Iomraidhean Croise  

Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.


Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí.


Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.”


Tabi ẹ kò kà ninu ìwé Òfin pé iṣẹ́ àwọn alufaa ninu Tẹmpili ní Ọjọ́ Ìsinmi a máa mú wọn ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́? Sibẹ wọn kò jẹ̀bi.


Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣe iṣẹ́ kan, ẹnu ya gbogbo yín.


Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan