Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:22 - Yoruba Bible

22 Nítorí pé Mose fun yín ní òfin ìkọlà, ẹ̀ ń kọlà fún eniyan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn òfin yìí kò bẹ̀rẹ̀ pẹlu Mose, àwọn baba-ńlá wa ni ó dá a sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Nitori eyi ni Mose fi ìkọlà fun nyin (kì iṣe nitoriti iṣe ti Mose, ṣugbọn ti awọn baba); nitorina ẹ si nkọ enia ni ilà li ọjọ isimi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:22
6 Iomraidhean Croise  

Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un.


Tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, wọn yóo kọ ilà abẹ́ fún ọmọ náà.


Ọlọrun wá bá a dá majẹmu, ó fi ilà kíkọ ṣe àmì majẹmu náà. Nígbà tí ó bí Isaaki, ó kọ ọ́ nílà ní ọjọ́ kẹjọ. Isaaki bí Jakọbu. Jakọbu bí àwọn baba-ńlá wa mejila.


Kókó ohun tí mò ń sọ ni pé òfin tí ó dé lẹ́yìn ọgbọnlenirinwo (430) ọdún kò lè pa majẹmu tí Ọlọrun ti ṣe rẹ́. Ìlérí tí Ọlọrun ti ṣe kò lè torí rẹ̀ di òfo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan