Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:19 - Yoruba Bible

19 Mo ṣebí Mose ti fun yín ní Òfin? Sibẹ kò sí ẹnìkan ninu yín tí ó ń ṣe ohun tí òfin wí. Nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

19 Mose kò ha fi ofin fun yin, kò si ẹnikẹni ninu nyin ti o pa ofin na mọ́? Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá ọ̀na lati pa mi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:19
27 Iomraidhean Croise  

Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.


Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’


Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin gbọ́, wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi pa á. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, nítorí ìyàlẹ́nu ni ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo eniyan.


Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?” Ṣugbọn wọn kò fọhùn.


Lẹsẹkẹsẹ àwọn Farisi jáde lọ láti gbìmọ̀ pọ̀ pẹlu àwọn alátìlẹ́yìn Hẹrọdu lórí ọ̀nà tí wọn yóo gbà pa á.


Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.


Nígbà náà ni wọ́n tún ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ó jáde kúrò ní àrọ́wọ́tó wọn.


Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu.


Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun.


Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn.


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.


Àwọn kan ninu àwọn ará Jerusalẹmu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ẹni tí wọ́n fẹ́ pa kọ́ yìí?


Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa.


Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin.


Nítorí àwọn tí wọ́n kọlà pàápàá kì í pa gbogbo òfin mọ́. Ṣugbọn wọ́n fẹ́ kí ẹ kọlà kí wọ́n máa fi yín fọ́nnu pé àwọn mu yín kọlà.


Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’


nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin, tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan