Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:15 - Yoruba Bible

15 Ẹnu ya àwọn Juu, wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe mọ ìwé tó báyìí nígbà tí kò lọ sí ilé-ìwé?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Ẹnu si yà awọn Ju, nwọn wipe, ọkunrin yi ti ṣe mọ̀ iwe, nigbati ko kọ́ ẹ̀kọ́?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:15
18 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò mọ̀wé kà.


Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí?


Nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.


Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.


Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í.


Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí wá a níbi àjọ̀dún náà, wọ́n ń bèèrè pé, “Níbo ni ó wà?”


Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu.


Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀hún bá dáhùn pé, “Ẹnikẹ́ni kò sọ̀rọ̀ bí ọkunrin yìí rí!”


Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.”


Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu.


Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan