Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:14 - Yoruba Bible

14 Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Nigbati ajọ de arin Jesu gòke lọ si tẹmpili o si nkọ́ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:14
16 Iomraidhean Croise  

OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.”


“Ní ọjọ́ keji, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mejila, àgbò meji, ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.


“Ní ọjọ́ kẹta, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mọkanla, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.


Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú.


Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!


Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili lojoojumọ. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin, pẹlu àtìlẹ́yìn àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ń wá ọ̀nà láti pa á,


Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀.


Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.”


Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò àjọ̀dún àwọn Juu nígbà tí wọn ń ṣe Àjọ̀dún Ìpàgọ́ ní aṣálẹ̀.


Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀.


Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi.


Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó tún lọ sí Tẹmpili. Gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá jókòó, ó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.


Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan