Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:47 - Yoruba Bible

47 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní ìyè ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

47 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

47 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:47
15 Iomraidhean Croise  

Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?”


Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè.


Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.


A kò ní dá ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lẹ́bi. Ṣugbọn a ti dá ẹni tí kò bá gbà á gbọ́ lẹ́bi ná, nítorí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí Ọlọrun kanṣoṣo gbọ́.


Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, ṣugbọn ibinu Ọlọrun wà lórí rẹ̀.


“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ gbọ́, olúwarẹ̀ ní ìyè ainipẹkun, kò ní wá sí ìdájọ́, ṣugbọn ó ti ré ikú kọjá, ó sì ti bọ́ sinu ìyè.


Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.”


Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”


Ṣugbọn oúnjẹ tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ ni èyí tí ó jẹ́ pé bí ẹnìkan bá jẹ ninu rẹ̀, olúwarẹ̀ kò ní kú.


Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.”


Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ní ìyè ainipẹkun, èmi yóo sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.


Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan