Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:44 - Yoruba Bible

44 Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi àfi bí Baba tí ó rán mi níṣẹ́ bá fà á wá, èmi óo wá jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

44 Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

44 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:44
22 Iomraidhean Croise  

Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!


Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada? Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù? Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere; ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.


OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè. Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.


Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́, mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn.


Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde.


Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.


Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.”


Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́.


Ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Gbogbo wọn ni Ọlọrun yóo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.’ Gbogbo ẹni tí ó bá gba ọ̀rọ̀ Baba, tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, á wá sọ́dọ̀ mi.


Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.”


Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi.


Nítorí anfaani ni èyí fun yín, kì í ṣe pé kí ẹ gba Kristi gbọ́ nìkan ni, ṣugbọn pé ẹ̀ ń jìyà fún Kristi.


nígbà tí a sin yín ninu omi ìrìbọmi, tí ẹ tún jinde nípa igbagbọ pẹlu agbára Ọlọrun tí ó jí Kristi dìde ninu òkú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan