Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:42 - Yoruba Bible

42 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ṣebí Jesu ọmọ Josẹfu ni; ẹni tí a mọ baba ati ìyá rẹ̀? Ó ṣe wá sọ pé, láti ọ̀run ni òun ti sọ̀kalẹ̀ wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? Ẽtiṣe tí ó wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:42
13 Iomraidhean Croise  

Ṣebí gbẹ́nàgbẹ́nà ni, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Juda, ati Simoni? Ṣebí àwọn arabinrin rẹ̀ nìwọ̀nyí lọ́dọ̀ wa yìí?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́.


Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”


Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”


Kò sí ẹni tí ó tíì gòkè lọ sí ọ̀run rí àfi ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, èyí ni Ọmọ-Eniyan.”


nítorí pé mo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bíkòṣe láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́.


Tí ẹ bá wá rí Ọmọ-Eniyan tí ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́?


Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin.


Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá.


Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan