Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:41 - Yoruba Bible

41 Àwọn Juu wá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i nítorí ó wí pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

41 Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:41
14 Iomraidhean Croise  

Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá ń kùn; wọ́n ń sọ pé, “Eléyìí ń kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra, ó tún ń bá wọn jẹun.”


Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!”


Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?”


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́.


Èmi pàápàá ni oúnjẹ tí ó ń fún eniyan ní ìyè.


Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”


Ọpọlọpọ tí ó gbọ́ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí le, kò sí ẹni tí ó lè gba irú rẹ̀!”


Nítorí èyí, ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ̀, wọn kò tún bá a rìn mọ́.


Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.”


Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n.


Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan