Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:30 - Yoruba Bible

30 Wọ́n wá bi í pé, “Iṣẹ́ ìyanu wo ni ìwọ óo ṣe, tí a óo rí i, kí á lè gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni o óo ṣe?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

30 Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? Iṣẹ kini iwọ ṣe?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

30 Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ ààmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kín ní ìwọ ṣe?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:30
22 Iomraidhean Croise  

Ó sì fún wọn ní àmì kan ní ọjọ́ náà, tí wọn yóo fi mọ̀ pé OLUWA ni ó gba ẹnu òun sọ̀rọ̀. Ó ní, “Pẹpẹ yìí yóo wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ yóo sì fọ́n dànù.”


Pẹpẹ náà wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ sì fọ́n dànù gẹ́gẹ́ bí wolii náà ti sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA.


Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́.


“Bí Farao bá wí pé kí ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún òun kí òun lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, kí ìwọ Mose sọ fún Aaroni pé kí ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ọba, kí ọ̀pá náà lè di ejò.”


Tí wọn ń wí pé: “Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá, kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i. Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́ kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”


Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.” Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú.


Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n.


Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.”


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́.


Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?”


(Ní àkókò yìí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ ra oúnjẹ ninu ìlú.)


Nígbà tí àwọn eniyan rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, wọ́n ní, “Dájúdájú, eléyìí ni wolii Ọlọrun náà tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”


Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.


Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ̀yin ti rí mi, sibẹ ẹ kò gbàgbọ́.


Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.”


Nítorí àwọn Juu ń bèèrè àmì: àwọn Giriki ń lépa ọgbọ́n;


Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan