Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:19 - Yoruba Bible

19 Lẹ́yìn tí wọ́n ti wa ọkọ̀ bí ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin wọ́n rí Jesu, ó ń rìn lórí òkun, ó ti súnmọ́ etí ọkọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

19 Nigbati nwọn wà ọkọ̀ to bi ìwọn furlongi mẹdọgbọn tabi ọgbọ̀n, nwọn ri Jesu nrìn lori okun, o si sunmọ ọkọ̀; ẹ̀ru si bà wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:19
16 Iomraidhean Croise  

òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.


OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi; OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae.


OLUWA lágbára lókè! Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ, ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ.


Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun. Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun.


Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i.


Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu.


Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.


Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ.


“Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín.


Ni omi òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nítorí afẹ́fẹ́ líle ń fẹ́.


Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”


Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀.


Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan