Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:12 - Yoruba Bible

12 Lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ ẹja ní àjẹtẹ́rùn, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó oúnjẹ tí ó kù jọ, kí ohunkohun má baà ṣòfò.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:12
12 Iomraidhean Croise  

Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.”


Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo àwọn ìlú olódi ati ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, wọ́n sì gba ilé tí ó kún fún ọpọlọpọ àwọn nǹkan dáradára, ati kànga, ọgbà àjàrà, igi olifi ati ọpọlọpọ igi eléso, nítorí náà wọ́n jẹ wọ́n yó, wọ́n sanra, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ninu oore ńlá rẹ.


Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.


Ó fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó mú àwọn ọlọ́rọ̀ jáde lọ́wọ́ òfo.


Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ tí àbúrò yìí fi kó gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó bá lọ sí ìlú òkèèrè, ó sá fi ìwà wọ̀bìà ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ní ìnákúnàá.


Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò.


Gbogbo àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n kó àjẹkù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila.


Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan