Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:7 - Yoruba Bible

7 Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:7
10 Iomraidhean Croise  

Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká, mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi; kò sí ààbò fún mi, ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.


Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀; a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀, ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.


Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò.


Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [


nítorí angẹli Oluwa a máa wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti rú omi adágún náà pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ bọ́ sinu adágún náà lẹ́yìn tí omi náà bá ti rú pọ̀, àìsànkáìsàn tí ó lè máa ṣe é tẹ́lẹ̀, yóo san.]


Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”


Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí.


Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà.


Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́, ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn, tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn, kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan