Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:6 - Yoruba Bible

6 Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:6
9 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì, ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà. Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi ní ọ̀nà tí mò ń rìn.


Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi, ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi. Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé, “Èmi nìyí, èmi nìyí.”


Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín, gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin, ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé! Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́?


“Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ó dáhùn pé, “Alàgbà, mo fẹ́ tún ríran ni!”


Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi.


Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji.


Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.”


Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.


Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan