Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:42 - Yoruba Bible

42 Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 Ṣugbọn emi mọ̀ nyin pe, ẹnyin tikaranyin kò ni ifẹ Ọlọrun ninu nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnrayín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:42
17 Iomraidhean Croise  

Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun.


Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un nípa ọmọ aráyé nítorí ó mọ ohun tí ó wà ninu wọn.


Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi.


“Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan.


Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á.


Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?


Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi.


Ẹni tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí tí ẹ kò fi gbọ́ ni èyí, nítorí ẹ kì í ṣe ẹni Ọlọrun.”


Ẹ kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́n. Bí mo bá sọ pé èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóo di òpùrọ́ bíi yín. Ṣugbọn mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.


Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni.


Ẹ má fẹ́ràn ayé tabi àwọn nǹkan ayé. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ayé kò ní ìfẹ́ sí Baba.


Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀?


Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí.


N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan