41 “Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan.
41 Emi kò gbà ogo lọdọ enia.
41 “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn.
nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ.
Kì í ṣe pé dandan ni fún mi pé kí eniyan jẹ́rìí gbè mí. Ṣugbọn mo sọ èyí fun yín kí ẹ lè ní ìgbàlà.
Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.
Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín.
Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?
Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè.
Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀.
Èmi kò wá ògo ti ara mi, ẹnìkan wà tí ó ń wá ògo mi, òun ni ó ń ṣe ìdájọ́.
Jesu dáhùn pé, “Bí mo bá bu ọlá fún ara mi, òfo ni ọlá mi. Baba mi ni ó bu ọlá fún mi, òun ni ẹ̀yin ń pè ní Ọlọrun yín.
Bẹ́ẹ̀ ni a kò wá ìyìn eniyan, ìbáà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín, tabi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn;
Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun.
Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ.”