Johanu 5:40 - Yoruba Bible40 Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè. Faic an caibideilBibeli Mimọ40 Ẹnyin kò si fẹ lati wá sọdọ mi, ki ẹnyin ki o le ni ìye. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè. Faic an caibideil |
“Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan; mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn? Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni; àbí n kò lágbára láti gba ni là? Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun, tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀, omi wọn gbẹ, òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa, wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.