Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:39 - Yoruba Bible

39 Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

39 Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ́ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni ìye ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

39 Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:39
51 Iomraidhean Croise  

Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA, a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.


Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.


Ó dàbí ìrì òkè Herimoni, tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni. Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun, àní, ìyè ainipẹkun.


O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí; ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ, ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.


Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un, àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.


Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.


Nítorí fìtílà ni òfin, ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,


Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA, kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀. Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀, kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì. Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ.


Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.


Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n: ìdààmú yóo bá wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n. Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀, ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?


Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.


Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?”


Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́, pé, ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ ni ó di pataki igun ilé.


“Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Wọ́n ní ìwé Mose ati ìwé àwọn wolii. Kí wọ́n fetí sí wọn.’


Ṣugbọn Abrahamu sọ fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí ohun tí Mose ati àwọn wolii kọ, bí ẹni tí ó ti kú bá tilẹ̀ jí dìde tí ó lọ bá wọn, kò ní lè yí wọn lọ́kàn pada.’ ”


Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ!


Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.


Ó bá sọ fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ tí mo sọ fun yín nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìyí, pé dandan ni kí ohun gbogbo tí a sọ nípa mi kí ó ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ wọ́n sílẹ̀ ninu ìwé Òfin Mose ati ninu ìwé àwọn wolii ati ninu ìwé Orin Dafidi.”


Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”


Ṣugbọn ẹlòmíràn ni ó ń jẹ́rìí mi, mo sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́ nípa mi.


Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́.


Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.


Bí ẹ bá gba Mose gbọ́, ẹ̀ bá gbà mí gbọ́, nítorí èmi ni ọ̀rọ̀ ìwé tí ó kọ bá wí.


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àbí ará Galili ni ìwọ náà? Lọ wádìí kí o rí i pé wolii kankan kò lè ti Galili wá!”


Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú.


Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.


Agiripa Ọba Aláyélúwà, ṣé ẹ gba àwọn wolii gbọ́? Mo mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́.”


Bí a bá wo inú Ìwé Mímọ́, a óo rí i pé àwọn wolii ti kéde ìyìn rere náà tẹ́lẹ̀ rí.


Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀.


OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu.


N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn.


“Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí.


Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.”


Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.


Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn.


Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú. A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ.


Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere.


Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.” Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan