Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:22 - Yoruba Bible

22 Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Nitoripe Baba ki iṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:22
23 Iomraidhean Croise  

níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀; ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.


níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.


Ìwọ ọdọmọkunrin, máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ, kí inú rẹ máa dùn; máa ṣe bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́, ati bí ó ti tọ́ lójú rẹ. Ṣugbọn ranti pé, Ọlọrun yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí o bá ṣe.


Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.


Nítorí Ọmọ-Eniyan yóo wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli rẹ̀, yóo wá fi èrè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.


Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé.


Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un.


Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀.


Ó ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí òun ni Ọmọ-Eniyan.


Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”


Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè.


Nítorí ó ti yan ọjọ́ tí yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé nípa ọkunrin tí ó ti yàn. Ó fi òtítọ́ èyí han gbogbo eniyan nígbà tí ó jí ẹni náà dìde kúrò ninu òkú.”


ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu.


Nítorí gbogbo wa níláti lọ siwaju Kristi bí a ti rí, láti lọ jẹ́ ẹjọ́. Níbẹ̀ ni olukuluku yóo ti gba ohun tí ó tọ́ sí i fún oríṣìíríṣìí ìwà tí ó ti hù nígbà tí ó wà ninu ara, ìbáà ṣe rere, ìbáà ṣe burúkú.


Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀.


Ṣugbọn wọn óo dáhùn fún ìwà wọn níwájú ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ìdájọ́ alààyè ati òkú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan