Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:21 - Yoruba Bible

21 Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti njí okú dide, ti o si nsọ wọn di ãye; bẹ̃li Ọmọ si nsọ awọn ti o fẹ di ãye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:21
14 Iomraidhean Croise  

Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.”


Nígbà tí ọba Israẹli ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù rẹ̀ hàn, ó sì wí pé, “Èmi ha í ṣe Ọlọrun tí ó ní agbára ikú ati ìyè bí, tí ọba Siria fi rò wí pé mo lè wo eniyan sàn kúrò ninu ẹ̀tẹ̀? Èyí fi hàn pé ó ń wá ìjà ni.”


Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè.


Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un.


Ẹ̀mí ní ń sọ eniyan di alààyè, ẹran-ara kò ṣe anfaani kankan. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ba yín sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ati ti ìyè.


Kí ló ṣe wá di ohun tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò lè gbàgbọ́ pé Ọlọrun a máa jí òkú dìde?”


Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín.


Ó wà ninu àkọsílẹ̀ pé, “Adamu, ọkunrin àkọ́kọ́ di alààyè;” ṣugbọn Adamu ìkẹyìn jẹ́ ẹ̀mí tí ó ń sọ eniyan di alààyè.


“ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé, èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun, kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi. Mo lè pa eniyan, mo sì lè sọ ọ́ di ààyè. Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́, mo sì lè wò ó sàn. Bí mo bá gbá eniyan mú, kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan