Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:20 - Yoruba Bible

20 Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

20 Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:20
17 Iomraidhean Croise  

“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.


Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”


Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.”


Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.


Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba.


N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín.


Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.”


Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀.


Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, tí àwọn òkú yóo gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun, àwọn tí ó bá gbọ́ yóo yè.


tí wọn yóo sì jáde. Àwọn tí ó ti ṣe rere yóo jí dìde sí ìyè, àwọn tí ó ti ṣe ibi yóo jí dìde sí ìdálẹ́bi.


Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan