Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:17 - Yoruba Bible

17 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:17
15 Iomraidhean Croise  

Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀; tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè.


Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run, ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi? Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun, tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan, tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀. Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó, ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó, ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì.


Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín.


kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé?


Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.


Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun.


Dandan ni fún mi kí n ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi ní ojúmọmọ, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ ṣú ná, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè ṣiṣẹ́.


Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.”


Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé: ‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé, tí à ń rìn kiri, tí a wà láàyè.’ Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní, ‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’


Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan.


Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn.


Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.


Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan