Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:15 - Yoruba Bible

15 Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Ọkunrin na lọ, o si sọ fun awọn Ju pe, Jesu li ẹniti o mu on larada.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:15
12 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn ọkunrin náà jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọpọlọpọ eniyan, ó ń rán ọ̀rọ̀ náà mọ́ ẹnu, tóbẹ́ẹ̀ tí Jesu kò fi lè wọ inú ìlú ní gbangba mọ́, ṣugbọn ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí eniyan. Sibẹ àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ibi gbogbo.


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


“Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?”


Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!”


Wọ́n bi í pé, “Ta ni ẹni náà tí ó sọ fún ọ pé kí o ru ẹni, kí o máa rìn?”


Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun.


Àwọn Farisi tún bi ọkunrin náà bí ó ti ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé, “Ó lẹ amọ̀ mọ́ mi lójú, mo lọ bọ́jú, mo bá ríran.”


Ọkunrin náà sọ fún wọn pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o, tabi ẹlẹ́ṣẹ̀ kọ́, èmi kò mọ̀. Nǹkankan ni èmi mọ̀: afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, mo ríran.”


Ọkunrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ohun ìyanu ni èyí! Ẹ kò mọ ibi tí ó ti yọ wá, sibẹ ó là mí lójú.


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan