Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:14 - Yoruba Bible

14 Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:14
23 Iomraidhean Croise  

Ní àkókò ìyọnu Ahasi ọba, ó túbọ̀ ṣe alaiṣootọ sí OLUWA ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.


Ṣugbọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ìsinmi tán, wọ́n tún ṣe nǹkan burúkú níwájú rẹ, o sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n ronupiwada tí wọ́n sì gbadura sí ọ, o gbọ́ lọ́run, lọpọlọpọ ìgbà ni o sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.


OLUWA jẹ mí níyà pupọ, ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.


Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé, n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀.


Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.


OLUWA, ṣàánú fún mi! Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú. Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,


OLUWA yóo gbà mí là, a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.


Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa?


Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí wúwú tí ó wú yìí bá jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun rẹ̀ bá sì funfun; kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí oówo.


“Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, ṣugbọn tí ẹ tún kẹ̀yìn sí mi,


Tí ó bá rú u fún ìdúpẹ́, yóo rú u pẹlu àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, tí a fi òróró pò, ati àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró lé lórí, pẹlu àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná ṣe, tí a fi òróró pò dáradára.


Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.”


Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”


Ṣugbọn ọkunrin náà tí Jesu wòsàn kò mọ ẹni tí ó wo òun sàn, nítorí pé eniyan pọ̀ níbẹ̀, ati pé Jesu ti yẹra kúrò níbẹ̀.


Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji.


Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”]


Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan