Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:10 - Yoruba Bible

10 Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:10
19 Iomraidhean Croise  

“Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi; bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú, tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo; bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín, tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín, tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ;


OLUWA ní kí ẹ ṣọ́ra fún ẹ̀mí yín, ẹ má máa ru ẹrù ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ má gbé ẹrù wọ ẹnubodè Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.


Ṣugbọn bí ẹ kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù wọ inú Jerusalẹmu lọ́jọ́ ìsinmi, n óo ṣá iná sí ẹnubodè Jerusalẹmu, yóo jó àwọn ààfin rẹ̀, kò sì ní ṣe é pa.’ ”


Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí.


Àwọn Farisi wí fún un pé, “Wò bí wọn ti ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi!”


Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?” Ṣugbọn wọn kò fọhùn.


Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!”


Wọ́n bá pada lọ láti lọ tọ́jú turari olóòórùn dídùn ati ìpara tí wọn fi ń tọ́jú òkú. Ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n sinmi gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí.


Àwọn kan ninu àwọn Farisi sọ pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi?”


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó mú mi lára dá ni ó sọ pé kí n ká ẹní mi, kí n máa rìn.”


Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn.


Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Ẹ̀yin ń kọ ilà ní Ọjọ́ Ìsinmi kí ẹ má baà rú òfin Mose, ẹ wá ń bínú sí mi nítorí mo wo eniyan sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi!


Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan