Johanu 4:53 - Yoruba Bible53 Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́. Faic an caibideilBibeli Mimọ53 Bẹ̃ni baba na mọ̀ pe, ni wakati kanna ni, ninu eyi ti Jesu wi fun u pe, Ọmọ rẹ yè: on tikararẹ̀ si gbagbọ́, ati gbogbo ile rẹ̀. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní53 Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀. Faic an caibideil |