Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:52 - Yoruba Bible

52 Ìjòyè náà wádìí lọ́wọ́ wọn nípa àkókò tí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Lánàá, ní nǹkan bí aago kan ni ibà náà lọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

52 Nigbana li o bère wakati ti o bẹ̀rẹ si isàn lọwọ wọn. Nwọn si wi fun u pe, Li ana, ni wakati keje, ni ibà na fi i silẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:52
4 Iomraidhean Croise  

Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà.


Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.” Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an.


Bí ó ti ń lọ, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá pàdé rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Ọmọ rẹ ti gbádùn.”


Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan