Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:5 - Yoruba Bible

5 Ó dé ìlú Samaria kan tí ń jẹ́ Sikari, lẹ́bàá ilẹ̀ tí Jakọbu fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nigbana li o de ilu Samaria kan, ti a npè ni Sikari, ti o sunmọ eti ilẹ biri nì, ti Jakọbu ti fifun Josefu, ọmọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:5
9 Iomraidhean Croise  

Ó ra ilẹ̀ ibi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní ọgọrun-un (100) gẹsita lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu.


Dípò kí n fún àwọn arakunrin rẹ ní Ṣekemu, tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè, níbi tí mo jagun gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori, ìwọ ni mo fún.”


Ó ní, “Nítòótọ́, ọ̀rọ̀ ìbáwí tí OLUWA pàṣẹ pé kí ó sọ sí pẹpẹ Bẹtẹli, ati gbogbo pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà káàkiri ní àwọn ìlú Samaria yóo ṣẹ.”


Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é.


Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?”


Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.”


Kànga kan tí ó ní omi wà níbẹ̀, tí Jakọbu gbẹ́ nígbà ayé rẹ. Jesu jókòó létí kànga náà ní nǹkan bí agogo mejila ọ̀sán, àárẹ̀ ti mú un nítorí ìrìn àjò tí ó rìn.


(Ní àkókò yìí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ ra oúnjẹ ninu ìlú.)


Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan