Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:46 - Yoruba Bible

46 Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

46 Bẹ̃ni Jesu tún wà si Kana ti Galili, nibiti o gbé sọ omi di waini. Ọkunrin ọlọla kan si wà, ẹniti ara ọmọ rẹ̀ kò da ni Kapernaumu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

46 Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:46
14 Iomraidhean Croise  

Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro; n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”


Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a; wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn.


“N óo pada sí ibùgbé mi títí wọn yóo fi mọ ẹ̀bi wọn, tí wọn yóo sì máa wá mi nígbà tí ojú bá pọ́n wọn.”


Obinrin Kenaani kan tí ó ń gbé ibẹ̀ bá jáde, ó ń kígbe pé, “Ṣàánú mi, Oluwa, ọmọ Dafidi. Ẹ̀mí èṣù ní ń da ọdọmọbinrin mi láàmú.”


Lẹ́yìn tí ó kúrò ní Nasarẹti, ó ń lọ gbè Kapanaumu tí ó wà lẹ́bàá òkun ní agbègbè Sebuluni ati Nafutali.


Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”


Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ”


Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un.


nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila. Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.


Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanaumu, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ bíi mélòó kan.


Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan.


Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan