Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:40 - Yoruba Bible

40 Nígbà tí àwọn ará Samaria dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Ó bá dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

40 Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:40
15 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.”


Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, má jẹ́ kí ó bọ́, pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.


Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ, títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi, ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.


Ìwọ ìrètí Israẹli, olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro. Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà? Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?


Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Ṣugbọn wọ́n bẹ̀ ẹ́ pupọ pé, “Dúró lọ́dọ̀ wa, ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ ti ṣú.” Ni ó bá bá wọn wọlé, ó dúró lọ́dọ̀ wọn.


Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní,


Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.”


Ọpọlọpọ àwọn mìíràn tún gbàgbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Lẹ́yìn ọjọ́ meji, Jesu jáde kúrò níbẹ̀ lọ sí Galili.


Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà.


Inú àwọn eniyan dùn pupọ ní ìlú náà.


Wò ó! Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà, mò ń kan ìlẹ̀kùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi, tí ó ṣílẹ̀kùn, n óo wọlé tọ̀ ọ́ lọ, n óo bá a jẹun, òun náà yóo sì bá mi jẹun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan