4 Ó níláti gba ààrin ilẹ̀ Samaria kọjá.
4 On kò si le ṣaima kọja lãrin Samaria.
4 Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria.
Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá.
Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá mi kiri? Ẹ kò mọ̀ pé dandan ni fún mi kí n wà ninu ilé Baba mi?”
Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá,